11 Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti ibi mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn.
12 Gbogbo àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ ọ̀kọrin: Ásáfù, Hémánì, Jédútúnì àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ túntún wọ́n ń lo ohun èlò orin kínnbálì, hápù àti líà. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfaà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn.
13 Àwọn afọ̀npè àti àwọn ọ̀kọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan soso, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun Olúwa. Wọ́n fi ìpè, kíḿbálì àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sokè láti fi yin Olúwa, wọ́n ń kọrin pé:“Ó dára;ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.”Nígbà náà ni ìkùku ojú ọ̀run kún inú tẹ́ḿpìlì Olúwa,
14 Tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò leè ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùku náà, nítorí ògo Olúwa kún inú tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run.