2 Kíróníkà 5:5-11 BMY

5 Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì ni ó mú wọn gòkè wá;

6 Nígbà náà ni ọba Sólómónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì tí ó pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò leè kà tán rúbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò leè mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó.

7 Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀ri ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù.

8 Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró.

9 Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí ori àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú ibi mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde. Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí.

10 Kò sí ohun kan nínú àpótí ẹ̀rí náà bí kò ṣe síléètì méjì tí Mósè fi sínú rẹ̀ ní Hórébù, ní ìgbà tí Olúwa fi bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì.

11 Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti ibi mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn.