1 Nígbà tí Sólómónì sì ti parí àdúrà, iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó ọrẹ sísun àti ẹbọ, ògo Ọlọ́run sì kún ilé Olúwa.
2 Àwọn àlùfáà wọn kò sì le wo ilé Olúwa náà nítorí pé ògo Olúwa kún un.
3 Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí iná tí ó ń sọ̀kalẹ̀ àti ògo Olúwa lórí ilé Olúwa náà, wọ́n sì kúnlẹ̀ lórí eékún wọn pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀, wọ́n sì sin Olúwa, wọ́n sì fi ìyìn fún Olúwa wí pé,“Nítorí tí ó dára;àánú rẹ̀ sì dúró títí láéláé.”
4 Nígbà náà ọba àti gbogbo àwọn ènìyàn sì rú ẹbọ níwájú Olúwa.