9 Nígbà náà ni ó sì fún ọba ní ọgọ́fà talẹ́ntì wúrà (120). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iye tùràrí, àti òkúta iyebíye. Kò sì tíì sí irú tùràrí yí gẹ́gẹ́ bí èyí tí ayaba Ṣébà fifún ọba Sólómónì.
10 Àwọn ènìyàn Húrámù àti àwọn ọkùnrin Sólómónì gbé wúrà wá láti Ófírì, wọ́n sì tún gbé igi álígúmù pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.
11 Ọba sì lo igi álígúmù náà láti fi ṣe àtẹ̀gùn fún ilé Olúwa àti fún ilé ọba àti láti fi ṣe dùùrù àti ohun ọ̀nà orin fún àwọn akọrin. Kò sì sí irú rẹ̀ tí a ti rírí ní ilẹ̀ Júdà.
12 Ọba Sólómónì fún ayaba Ṣébà ní gbogbo ohun tí ó bèèrè fún àti ohun tí ó wù ú; ó sì fi fún un ju èyí tí ó mú wá fún un lọ. Nígbà náà ni ó lọ ó sì padà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ìlú rẹ̀.
13 Ìwọ̀n wúrà tí Sólómónì gbà ní ọdún kan sì jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà talẹ́ntì (666),
14 Láì tíì ka àkójọpọ̀ owó ìlú tí ó wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò àti àwọn ọlọ́jà. Àti pẹ̀lú gbogbo àwọn ọba Árábíà àti àwọn báálẹ̀ ilẹ̀ náà mu wúrà àti fàdákà wá fún Sólómonì.
15 Ọba Solómónì sì ṣe igba (200) àṣà wúrà lílù: ẹgbẹ̀ta (6,000) àsà tí a fi òlùlù wúrà sí òkànkàn sékélì.