6 Nígbà náà, Jéhù kọ lẹ́tà kejì síwọn, wí pé, “Tí ìwọ bá wà ní ìhà tèmi, tí o sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, mú orí àwọn ọmọkùnrin ọ̀gá à rẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ní Jésérẹ́lì ní ìwòyí ọ̀la.”Nísinsìn yìí, àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba, àádọ́rin wọn sì wà pẹ̀lú àwọn adarí ọkùnrin ní ìlú àwọn tí wọ́n ń bọ́ wọn.
7 Nígbà tí ìwé náà dé àwọn ọkùnrin wọ̀nyí mú gbogbo àwọn ọmọ aládé bìnrin, wọ́n sì pa gbogbo àádọ́rin wọn. Wọ́n gbé orí i wọn sí inú apẹ̀rẹ̀, wọ́n fi ránṣẹ́ sí Jéhù ní Jésérẹ́lì.
8 Nígbà tí ìránṣẹ́ náà dé, ó sọ fún Jéhù, “Wọ́n ti gbé orí àwọn ọmọ aládé bìnrin náà wá.”Nígbà náà Jéhù pàṣẹ, “Kó wọn sí ẹ̀bú méjì sí àbáwọlé ìlẹ̀kùn ìlú ńlá títí di òwúrọ̀.”
9 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Jéhù jáde lọ. Ó dúró níwájú gbogbo àwọn ènìyàn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin jẹ́ aláìjẹ̀bi. Èmi ni mo dìtẹ̀ sí ọ̀gá mi, tí mo sì pa á, ṣùgbọ́n ta ni ó pa gbogbo àwọn wọ̀nyí!?
10 Nígbà yìí, kò sí ọ̀rọ̀ kan tí Olúwa ti sọ sí ilé Áhábù tí yóò kùnà. Olúwa ti ṣe ohun tí ó ṣèlérí nípaṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ Èlíjà.”
11 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhù pa gbogbo ẹni tí ó kù ní ilé Áhábù, pẹ̀lú pẹ̀lú gbogbo àwọn ọkùnrin ìjòyè rẹ̀, àwọn ọ̀rẹ́ ẹ rẹ̀ tímọ́-tímọ́ àti àwọn àlùfáà rẹ̀, láì ku ẹni tí ó yọ nínú ewu fún un.
12 Jéhù jáde lọ, ó sì lọ sí ọ̀kánkán Ṣamáríà. Ní Bẹti-Ékédì tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn.