1 Nígbà tí Ataláyàyà ìyá Áhásáyà rí i wí pé ọmọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀ṣíwájú láti pa gbogbo ìdílé ọba náà run.
2 Ṣùgbọ́n Jéhóṣébà ọmọbìnrin ọba Jéhórámù àti arábìnrin Áhásáyà, mú Jóásì ọmọ Áhásáyà, ó sì jí i lọ kúrò láàárin àwọn ọmọ aládé bìnrin ti ọba náà, tí ó kù díẹ̀ kí a pa. Ó gbé òhun àti olùtọ́jú rẹ̀ sínú ìyẹ̀wù láti fi pamọ́ kúrò fún Ataláyà; Bẹ́ẹ̀ ni a kò pa á.
3 Ó wà ní ìpamọ́ pẹ̀lú olùtọ́jú ní ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọdún mẹ́fà nígbà tí Ataláyà fi jọba lórí ilẹ̀ náà.
4 Ní ọdún kéje, Jéhóíádà ránṣẹ́ sí àwọn olóórí ní ọrọrún àwọn balógun àti àwọn olùṣọ́, ó sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Ó ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, ó sì fi wọ́n sí abẹ́ ìbúra nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Níbẹ̀ ni ó fi ọmọkùnrin ọba hàn wọ́n.