2 Ọba 11:14-20 BMY

14 Ó wò ó, níbẹ̀ ni ọba, tí ó dúró lẹ́bàá òpó, gẹ́gẹ́ bí àṣà ti rí. Àwọn ìjòyè àti àwọn afọ̀npè wà ní ẹ̀bá ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilé náà sì ń yọ̀ wọ́n sì ń fọ̀npè pẹ̀lú. Nígbà náà Ataláyà fa aṣọ ìgúnwà rẹ̀ ya. Ó sì kégbe pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”

15 Jéhóíádà àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrin àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.”

16 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi agbára mú un bí ó ti dé ibi tí àwọn ẹṣin tí ń wọ ilẹ̀ ààfin àti níbẹ̀ ni a ti pa á.

17 Nígbà náà ni Jéhóíádà dá májẹ̀mú láàrin Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrin ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú.

18 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Báálì wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mátanì àlùfáà Báálì níwájú àwọn pẹpẹ.Nígbà náà, Jéhóíádà àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

19 Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọọrún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú àyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba.

20 Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, pẹ̀lú ìlú ńlá náà sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorí a pa Ataláyà pẹ̀lú idà náà ní ààfin.