1 Ní ọdún keje tí Jéhù, Jóásì di ọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ogójì ọdún. Orúkọ ìyá a rẹ̀ a máa jẹ́ Síbíyà: Ó wá láti Beeriṣébà.
2 Jóásì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọdún tí Jéhóíádà àlùfáà fi àsẹ fún un.
3 Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò sí wọn ní ìdí; Àwọn ènìyàn sì tẹ̀ṣíwájú láti máa rú ẹbọ àti sísun tùràrí níbẹ̀.
4 Jóásì sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a múwá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.
5 Jẹ́ kí gbogbo àlùfáà gba owó náà lọ́wọ́ ọ̀kan nínú àwọn akápò. Kí a sì lò ó fún túntún ohunkóhun tí ó bá bàjẹ́ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.”