26 Olúwa ti rí bí olúkúlùkù yálà ẹrú tàbí òmìnira, ti ń jìyà gidigidi; kò sì sí ẹnìkan tí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́.
27 Láti ìgbà tí Olúwa kò ti wí pé òhun yóò bu àbùkù lu orúkọ Ísírẹ́lì láti abẹ́ ọ̀run. Ó gbà wọ́n là, lọ́wọ́ Jéróbóámù ọmọ Jéhóásì.
28 Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jéróbóámù, gbogbo ohun tí ó ṣe àti gbogbo àwọn àṣeyọrí ológun rẹ̀ àti bí ó ṣe gbà padà fún Ísírẹ́lì lápapọ̀. Dámásíkù àti Hámátì, tí ó ti jẹ́ ní Yáúdì, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì?
29 Jéróbóámù sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, àwọn ọba Ísírẹ́lì Ṣekaríyà ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.