4 Ṣùgbọ́n ọba Ásíríà ríi wí pé Hóséà jẹ́ ọlọ́tẹ̀, nítorí ó ti rán ońsẹ́ sọ́dọ̀ ọba Éjíbítì, kò sì san owó òde mọ́ fún ọba Áṣíríà, gẹ́gẹ́ bí o ti máa ń ṣe ní ọdọdún. Nígbà náà ọba Áṣírìa fi agbára mú-ún, ó sì fi sínú túbú.
5 Ọba Ásíríà gòkè wá sí gbogbo ibi ilé náà, ó sì lọ sí Samáríà, ó sì dúró tìí fún ọdún mẹ́ta.
6 Ní ọdún kẹsàn-án ti Hóṣéà, ọba Áṣíríà mú Ṣamáríà ó sì kó Ísírẹ́lì lọ sí Áṣíríà. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ní Hálà, ní Gósánì ní ọ̀dọ̀ Hábónì àti ní ìlú àwọn ará Médáì.
7 Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Éjíbítì lábẹ́ agbára Fáráò ọba Éjíbítì. Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn
8 Wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Ísírẹ́lì tí ó ti paláṣẹ
9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìsọ́ sí ìlú tí a dábòbò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn.
10 Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ sókè àti ère òrìṣà lórí gbogbo igi túútúú