7 Gbogbo eléyìí ṣẹlẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti dẹ́sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde ní Éjíbítì lábẹ́ agbára Fáráò ọba Éjíbítì. Wọ́n sin ọlọ́run mìíràn
8 Wọn si tẹ̀lé ìwà orílẹ èdè tí Olúwa ti gbá kúrò níwájú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà ti ọba Ísírẹ́lì tí ó ti paláṣẹ
9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìsọ́ sí ìlú tí a dábòbò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn.
10 Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ sókè àti ère òrìṣà lórí gbogbo igi túútúú
11 Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n ṣun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búrubú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè.
12 Wọ́n sìn òrìsà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.”
13 Olúwa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi palaṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán síi yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”