2 Ọba 17:9-15 BMY

9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun ìríra sí Olúwa Ọlọ́run wọn kọ́ láti ilé ìsọ́ sí ìlú tí a dábòbò, wọ́n kọ́ ilé gíga fún ara wọn ní gbogbo ìlú wọn.

10 Wọ́n sì gbé àwọn òkúta tí a yà sọ́tọ sókè àti ère òrìṣà lórí gbogbo igi túútúú

11 Ní gbogbo ibi gíga, wọ́n ṣun tùràrí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú wọn. Wọ́n ṣe ohun búrubú tí ó rú ìbínú Olúwa sókè.

12 Wọ́n sìn òrìsà, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe èyí.”

13 Olúwa kìlọ̀ fún Ísírẹ́lì àti Júdà nípa gbogbo àwọn wòlíì wọn àti aríran: “Ẹ yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú yín. Kí ẹ ṣe òfin mi àti ìlànà mi, ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin tí Èmi palaṣẹ fún àwọn baba yín láti tẹ̀lé àti èyí tí mo rán síi yín nípa ìránṣẹ́ àwọn wòlíì mi.”

14 Ṣùgbọ́n wọn kò ní gbọ́, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́rùn lile gẹ́gẹ́ bí i ti baba wọn, ẹni tí kò gbà Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́.

15 Wọ́n kọ̀ ìlànà rẹ̀ àti májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú baba wọn àti ìkìlọ̀ tí ó ti fi fún wọn. Wọ́n tẹ̀lé òrìṣà aláìníláárí, àwọn fún rara wọn sì jẹ́ aláìníláárí. Wọ́n tẹ̀lé orílẹ̀ èdè tí ó yí wọn ká bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa ti kìlọ̀ fún wọn pé, “Má ṣe ṣe gẹ́gẹ́ bí wọn tí ń ṣe,” wọ́n sì ṣe ohun tí Olúwa ti kà léèwọ̀ fún wọn láti ṣe.