5 Heṣekáyà sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Kò sì sí ẹnìkan tí ó dàbí tirẹ̀ lára gbogbo àwọn ọba Júdà, bóyá kí ó tó jẹ tàbí lẹ́yìn rẹ̀.
6 Ó sún mọ́ Olúwa, kò sì dẹ́kun láti tì í lẹ́yìn: ó sì pa òfin Olúwa mọ́ tí ó ti fi fún Mósè.
7 Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà kò sì sìn-ín.
8 Láti ilé-ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Fílístínì run, àti títí dé Gásà àti agbègbè rẹ̀.
9 Ní ọdún kẹrin ọba Heṣekáyà, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hóséà ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì. Ṣálímánésérì ọba Áṣíríà yàn lára Ṣamáríà ó sì tẹ̀dó tì í.
10 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Ásíríà gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Ṣamáríà ní ọdún kẹfà Heṣekáyà tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì.
11 Ọba Áṣíríà lé Ísírẹ́lì kúrò ní Áṣíríà, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hálà, ní Gósánì létí odò Hábórì àti ní ìlú àwọn ará Médíà.