7 Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀; ó sì ń ṣe rere nínú gbogbo ohun tí ó dáwọ́lé. Ó ṣe ọ̀tẹ̀ sí ọba Ásíríà kò sì sìn-ín.
8 Láti ilé-ìṣọ́ títí dé ìlú olódi, ó sì pa àwọn ará Fílístínì run, àti títí dé Gásà àti agbègbè rẹ̀.
9 Ní ọdún kẹrin ọba Heṣekáyà, nígbà tí ó jẹ́ ọdún keje Hóséà ọmọ Élà ọba Ísírẹ́lì. Ṣálímánésérì ọba Áṣíríà yàn lára Ṣamáríà ó sì tẹ̀dó tì í.
10 Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta Ásíríà gbé e. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó Ṣamáríà ní ọdún kẹfà Heṣekáyà tí ó sì jẹ́ ọdún kẹsàn-án Hóṣéà ọba Ísírẹ́lì.
11 Ọba Áṣíríà lé Ísírẹ́lì kúrò ní Áṣíríà, wọ́n sì ṣe àtìpó wọn ní Hálà, ní Gósánì létí odò Hábórì àti ní ìlú àwọn ará Médíà.
12 Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wọn kò pa àṣẹ Olúwa Ọlọ́run wọn mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n ti dà májẹ̀mú rẹ̀ gbogbo èyí tí Móṣè ìránṣẹ́ Olúwa ti pa láṣẹ. Wọn kò fi etí wọn sílẹ̀ sí òfin wọn kò sì gbé wọn jáde.
13 Ní ọdún kẹrìnlá tí Heṣekáyà jọba, Ṣenakérúbù ọba Ásíríà kọlu gbogbo ìlú olódi ti Júdà ó sì pa wọ́n run.