16 Dẹtí sílẹ̀, Olúwa kí o sì gbọ́; la ojú ù rẹ, Olúwa, kí o sì rí i, gbọ́ ọ̀rọ̀ Ṣenakérúbù tí ó rán láti fi bú Ọlọ́run alààyè.
17 “Òtítọ́ ni, Olúwa, wí pé ọba Ásíríà ti pa orílẹ̀ èdè wọ̀nyìí run àti ilẹ̀ wọn.
18 Wọ́n ti ju òrìṣà wọn sínú iná wọn sì ti bà wọ́n jẹ́, nítorí pé wọn kì í ṣe Olúwa. Ṣùgbọ́n, wọ́n jẹ́ igi àti òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ ọ́ pẹ̀lú ọwọ́ ènìyàn.
19 Nísinsìn yìí Olúwa Ọlọ́run wa, gbà wá kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ìjọba lórí ilẹ̀ ayé le mọ̀ pé ìwọ nìkanṣoṣo ni, Olúwa Ọlọ́run wa.”
20 Nígbà náà Àìṣáyà ọmọ Ámósì rán oníṣẹ́ sí Heṣekíàyà pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ nípa ti Ṣenakérúbù ọba Ásíríà.
21 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀:“ ‘Wúndíá ọmọbìnrin Ṣíónìkẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà.Ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mùmi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ.
22 Ta ni ìwọ ti bú tí o sì kẹ́gàn rẹ̀?Lórí ta ni ìwọ ti gbé gbé ohùn rẹsókè tí ó sì gbé ojú sókè sí ọ ní ìgbéraga?Lórí ẹni mímọ́ ti Ísírẹ́lì!