27 “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọdúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbílọ àti bí ìwọ ṣe ikáanú rẹ: sí mi.
28 Ṣùgbọ́n ikáanú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi,Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imúrẹ àti ìjánú mi sí ẹnu rẹ,èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ’
29 “Èyí yóò jẹ́ àmìn fún ọ, ìwọ Heṣekíàyà:“Ọdún yìí ìwọ yóò jẹ ohun tí ó bá hù fún rara rẹ̀,àti ní ọdún kejì ohun tí ó bá hù jáde láti inú iyẹn.Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹta, gbìn kí o sì kórè,gbin ọgbà àjàrà kí o sì jẹ èṣo rẹ̀.
30 Lẹ́ẹ̀kan sí i ìyókù ti ilé Júdàyóò sì tún hu gbòǹgbòlábẹ́, yóò sì so èṣo lókè.
31 Láti inú Jérúsálẹ́mù ní àwọn ìyókù yóò ti wáàti láti orí òkè Ṣíónì ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó ṣá àsálà.Ìtara Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò ṣe èyí.
32 “Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa ṣọ nípa ti ọba Áṣíríà:“Kò ní wọ ìlú yìítàbí ta ọfà síbí.Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lúàpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.
33 Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá niyóò padà; kì yóò wọ ìlú ńlá yìí,ni Olúwa wí.