2 Ọba 2:9-15 BMY

9 Nígbà tí wọ́n rékọjá, Èlíjà sì wí fún Èlíṣà pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10 “Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Èlíjà wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

11 Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹsin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Èlíjà sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà.

12 Èlíṣà rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Ísírẹ́lì!” Èlíṣà kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.

13 Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Èlíjà ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jọ́dánì.

14 Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Èlíjà wà?” Ó bèèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, ó sì rékọjá.

15 Àwọn ọmọ wòlíì láti Jẹ́ríkò, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Èlíjà simi lé Èlíṣà.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojú bolẹ̀ níwájú rẹ̀.