24 Síwájú sí, Jòsíáyà sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Júdà àti ní Jérúsálẹ́mù. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hílíkíyà àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa.