2 Ọba 23:5-11 BMY

5 Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Júdà láti ṣun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Júdà àti àwọn tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Báálì, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.

6 Ó mú ère òrìṣà láti ilé Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì ní ìta Jérúsálẹ́mù, ó sì ṣun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí atíkè ó sì fọ́n ekuru náà sórí iṣà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀.

7 Ó sì wó ibùgbé àwọn tí ń ṣe panṣágà lọ́kùnrin o tí ojúbọ wọn lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún Áṣérà (òriṣà).

8 Jòṣíáyà kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Júdà ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Gébà sí Béríṣébà, níbi tí àwọn àlùfáà ti ṣun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ti Jóṣúà, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.

9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn.

10 Ó sì ba ohun mímọ́ Tófẹ́tì jẹ́, tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Beni-Hínómì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnìkan tí ó lè lò ó fún ẹbọ rírú fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin nínú iná sí Mólékì.

11 Ó sì kúrò láti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa, àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Júdà ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà. Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Nátanì-Mélékì. Jòṣíáyà sì ṣun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn.