1 Jéhórámù ọmọ Áhábù ó sì di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà ní ọdún kejìdínlógún ti Jéhósáfátì ọba Júdà, ó sì jọba fún ọdún méjìlá.
2 Ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, ṣùgbọ́n kì í ṣe bí ti ìyá àti bàbá rẹ̀ ti ṣe. Ó gbé òkúta ère ti Báálì tí baba rẹ̀ ti ṣe.
3 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi ara mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ Jéróbóámù ọmọ Nébátì, tí ó ti fi Ísírẹ́lì bú láti dẹ́ṣẹ̀; kò sì yí kúrò lọ́dọ̀ wọn.
4 Nísinsìn yìí Mésà ọba Móábù ń sin àgùntàn, ó sì gbọdọ̀ fi fún ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú ọgọ́rún ẹgbẹ̀rùnún ọ̀dọ́ àgùntàn àti pẹ̀lú irú ọgọ́runún ẹgbẹ̀rúnún (hundred thousand) àgbò.
5 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Áhábù, ọba Móábù ṣọ̀tẹ̀ lórí ọba Ísírẹ́lì.
6 Lásìkò ìgbà yìí ọba Jéhórámù jáde kúrò ní Ṣamáríà ó sì yí gbogbo Ísírẹ́lì nípò padà.
7 Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jéhóṣáfátì ọba Júdà: “Ọba Móábù sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Móábù jà?”“Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ,” Ó dáhùn. “Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”