12 Jèhóṣáfátì wí pé, “ọ̀rọ̀ Olúwa wà pẹ̀lú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì àti Jèhóṣáfátì àti ọba Édómù sọ̀ kalẹ̀ tọ̀ ọ́ lọ.
13 Èlíṣà wí fún ọba Ísírẹ́lì pé, “Kí ni àwa ní ṣe pẹ̀lú ara wa? Lọ sọ́dọ̀ wòlíì bàbá rẹ àti wòlíì ti ìyá rẹ.”“Rárá,” ọba Ísírẹ́lì dá a lóhùn, “nítorí Olúwa ni ó pe àwa ọba mẹ́tẹ̀ẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Móábù lọ́wọ́.”
14 Èlíṣà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pé Olúwa àwọn ọmọ ogun wà láyé, ẹni tí mo ń sìn tí èmi kò bá ní ọ̀wọ̀ fún ojú Jèhósáfátì ọba Júdà, Èmi kò ní wò ó tàbí èmi kì bá ti rí ọ.
15 Ṣùgbọ́n Nísinsìn yìí mú wá fún mi ohun èlò orin olókun.”Nígbà tí akọrin náà n kọrin, ọwọ́ Olúwa wá sórí Èlíṣà.
16 Ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: Jẹ́ kí àfonífojì kún fún ọ̀gbun.
17 Nítorí èyí ni Olúwa wí: O kò níí rí afẹ́fẹ́ tàbí òjò, bẹ́ẹ̀ ni àfonífojì yìí yóò kún pẹ̀lú omi, àti ìwọ àti ẹran ọ̀sìn àti pẹ̀lú àwọn ẹran yóò mu.
18 Èyí jẹ́ ohun tí kò lágbára níwájú Olúwa, yóò sì fi Móábù lé e yín lọ́wọ́ pẹ̀lú.