23 “Ẹ̀jẹ̀ ni èyí!” wọ́n wí pé, “Àwọn ọba wọ̀nyí lè ti jà kí wọn sì pa ara wọn ní ìpakúpa. Nísinsìn yìí sí àwọn ìkógun Móábù!”
24 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Móábù dé sí ibùdó ti Ísírẹ́lì, àwọn ará Ísírẹ́lì dìde, wọ́n sì kọlù wọ́n títí tí wọ́n fi sálọ. Àwọn ará Ísírẹ́lì gbógun sí ilẹ̀ náà wọ́n sì pa Móábù run.
25 Wọ́n sì wọ gbogbo ìlú náà olúkúlùkù ènìyàn, wọ́n ju òkúta sí gbogbo ohun dáradára orí pápá títí tí ó fi run. Wọ́n sì dá gbogbo orísun omi dúró wọ́n sì gé gbogbo orísun dáradára. Kíríháráṣétì nìkan ni wọ́n fi òkúta rẹ̀ sílẹ̀ ní àyè rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ológun pẹ̀lú kanakáná yíká, wọ́n sì kọlù ìlú náà.
26 Nígbà tí ọba Móábù rí i wí pé ogun náà le ju ti òun lọ, ó mú idà pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ọkùnrin (700) onídà láti jà pẹ̀lú ọba Édómù, ṣùgbọ́n wọn kò yege.
27 Nígbà náà ó mú àkọ́bí ọmọkùnrin rẹ̀, tí kò bá jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba, ó sì fi rú ẹbọ sísun ní orí ògiri ìlú. Wọ́n sì bínú lórí Ísírẹ́lì púpọ̀púpọ̀; wọ́n yọ́ kúrò wọ́n sì padà sí ìlú wọn.