5 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ikú Áhábù, ọba Móábù ṣọ̀tẹ̀ lórí ọba Ísírẹ́lì.
6 Lásìkò ìgbà yìí ọba Jéhórámù jáde kúrò ní Ṣamáríà ó sì yí gbogbo Ísírẹ́lì nípò padà.
7 Ó sì ránṣẹ́ yìí sí Jéhóṣáfátì ọba Júdà: “Ọba Móábù sì ṣọ̀tẹ̀ sí mi. Ṣé ìwọ yóò lọ pẹ̀lú mi láti lọ bá Móábù jà?”“Èmi yóò lọ pẹ̀lú rẹ,” Ó dáhùn. “Èmi jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà, ènìyàn rẹ bí ènìyàn mi, ẹṣin mi bí ẹṣin rẹ.”
8 “Nípa ọ̀nà wo ni àwa yóò gbà dójukọ wọ́n?” Ó bèèrè,“Lọ́nà ihà Ékírónì,” ó dáhùn.
9 Bẹ́ẹ̀ ni ọba Isírẹ́lì jáde lọ pẹ̀lú ọba Júdà àti ọba Édómù. Lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n yíká fún ọjọ́ méje. Àwọn ọmọ ogun wọn kò ní omi púpọ̀ fún ara wọn tàbí fún ẹranko tí ó wà pẹ̀lú wọn.
10 “Kí ni?” Ọba Ísírẹ́lì kígbe sókè. “Ṣé Olúwa pè àwa ọba mẹ́tẹ̀ta papọ̀ láti fi wá lé Móábù lọ́wọ́?”
11 Ṣùgbọ́n Jèhóṣáfátì sì wí pé, “Ṣé kò sí wòlíì Olúwa níbí, tí àwa ìbá ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀?”Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé, “Èlíṣà ọmọ Ṣáfátì wà níbí. Ó máa ṣábà bu omi sí ọwọ́ Èlíjàh.”