2 Ọba 5:1-7 BMY

1 Námánì jẹ́ olórí ogun ọba Árámù. Ó jẹ́ ènìyàn ńlá níwájú ọ̀gá rẹ̀, wọ́n sì bu ọlá fún un, nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ Olúwa fún wa ní ìṣẹ́gun fún Árámù. Ó jẹ́ alágbára, akọni ọkùnrin ṣùgbọ́n, ó dẹ́tẹ̀.

2 Nísinsìnyìí ẹgbẹgbẹ́ láti Árámù ti jáde lọ láti mú ọmọ obìnrin kékeré kan ní ìgbèkùn láti Ísírẹ́lì, ó sì sin ìyàwó Námánì.

3 Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samáríà! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

4 Námánì lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Ísírẹ́lì ti sọ.

5 “Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Árámù dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì.” Bẹ́ẹ̀ ni Námánì lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ talẹ́ńtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà (6,000) àti ìpàrọ̀ aṣọ mẹ́wàá.

6 Ìwé tí ó mú lọ sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì kà pé: “Pẹ̀lú ìwé yìí èmi ń rán ìránṣẹ́ mi Námánì sí ọ pé o lè wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.”

7 Bí ọba Ísírẹ́lì ti ka ìwé náà ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì wí pé, “Èmi ha jẹ́ Ọlọ́run? Ǹjẹ́ èmi le pa kí n sì mú wá sí àyè padà? Kí ni ó dé tí eléyìí rán ènìyàn sí mi láti wo àrùn ẹ̀tẹ̀ rẹ sàn, kí ẹ wo bí ó ti ń wá ọ̀nà láti wá ìjà pẹ̀lú mi!”