2 Ọba 5:13-19 BMY

13 Ìránṣẹ́ Námánì lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Baba mi, tí wòlíì bá ti sọ fún ọ láti ṣe ohun ńlá kan, ṣé ìwọ kì bá ti ṣe, mélòómélòó nígbà náà, nígbà tí ó sọ fún ọ pé, ‘Wẹ̀ kí o sì mọ́’!”

14 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ ó sì tẹ ara rẹ̀ bọ inú odò Jọ́dánì ní ìgbà méje, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún un, ẹran ara rẹ̀ sì tún padà sí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọkùnrin kékeré.

15 Nígbà náà Námánì àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ padà lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run. Ó sì dúró níwájú rẹ̀ ó sì wí pé, “Nísinsìnyí èmi mọ̀ pé kò sí Ọlọ́run ní gbogbo àgbáyé àyàfi ní Ísírẹ́lì nìkan. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn láti ọwọ́ ìránṣẹ́ rẹ.”

16 Wòlíì náà dáhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, ẹni tí mo ń sìn, èmi kò ní gba ohun kan,” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Námánì rọ̀ ọ́ láti gbàá, ó kọ̀.

17 “Tí o kò bá ní gba,” Námánì wí pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí èmi, ìránṣẹ́ rẹ fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹrù ẹrùpẹ̀ ìbaka méjì, nítorí láti òní lọ ìránṣẹ́ rẹ kì yóò rú ẹbọ sísun àti rúbọ sí ọ̀kan lára àwọn ọlọ́run mìíràn ṣùgbọ́n Olúwa.

18 Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rímónì láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rímónì, kí Olúwa dáríji ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”

19 Èlíṣà wí pé, “Má a lọ ní àlàáfíà.”Lẹ́yìn ìgbà tí Námánì tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà,