2 Ọba 5:18-24 BMY

18 Ṣùgbọ́n kí Olúwa kí ó dáríjì ìránṣẹ́ rẹ fún nǹkan yìí: Nígbà tí ọ̀gá mi wọ inú ilé Rímónì láti fi orí balẹ̀ tí ó sì fi ara ti ọwọ́ mi tí mo sì tẹ ara mi ba pẹ̀lú níbẹ̀. Nígbà tí èmi tẹ ara mi ba ní ilé Rímónì, kí Olúwa dáríji ìránṣẹ́ rẹ fún èyí.”

19 Èlíṣà wí pé, “Má a lọ ní àlàáfíà.”Lẹ́yìn ìgbà tí Námánì tí rin ìrìnàjò tí ó jìnnà,

20 Géhásì, ìránṣẹ́ Èlíṣà ènìyàn Ọlọ́run, ó wí fún ara rẹ̀ pé, “Ọ̀gá mi jẹ́ ẹni tí ó rọ̀ lórí Námánì, ará Árámù, nípa pé kò gba ohunkóhun ní ọwọ́ rẹ̀ ohun tí ó mú wá, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè, èmi yóò sá tẹ̀lé e èmi yóò sì gba ohun kan ńi ọwọ́ rẹ̀.”

21 Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì sáré tẹ̀lé Námánì. Nígbà tí Námánì rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáadáa?” ó béèrè.

22 “Gbogbo nǹkan wà dáadáa,” Géhásì dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Éfúráímù. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpàrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

23 Námánì wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Géhásì láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Géhásì.

24 Nígbà tí Géhásì wá sí ilẹ̀ gíga, ó sì mú nǹkan náà lọ́dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì gbé wọn kúrò ní ilé, ó sì rán ọkùnrin náà jáde ó sì lọ.