2 Ọba 5:21-27 BMY

21 Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì sáré tẹ̀lé Námánì. Nígbà tí Námánì rí i tí ó ń sáré tẹ̀lé e, ó sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ̀. “Ṣé gbogbo nǹkan wà dáadáa?” ó béèrè.

22 “Gbogbo nǹkan wà dáadáa,” Géhásì dá a lóhùn. “Ọ̀gá mi rán mi láti sọ wí pé, ‘Àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin méjì láti ọ̀dọ̀ ọmọ wòlíì wọ́n ṣẹ̀ ṣẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi láti orí òkè ìlú ti Éfúráímù. Jọ̀wọ́ fún wọn ní ẹ̀bùn fàdákà àti ìpàrọ̀ aṣọ méjì.’ ”

23 Námánì wí pé, “Ní gbogbo ọ̀nà, mú ẹ̀bùn méjì.” Ó sì rọ Géhásì láti gbà wọ́n, ó sì di ẹ̀bùn méjì náà ti fàdákà ní inú àpò méjì, pẹ̀lú ìpààrọ̀ aṣọ méjì, ó sì fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ méjì, wọ́n sì kó wọn lọ sọ́dọ̀ Géhásì.

24 Nígbà tí Géhásì wá sí ilẹ̀ gíga, ó sì mú nǹkan náà lọ́dọ̀ ìránṣẹ́ ó sì gbé wọn kúrò ní ilé, ó sì rán ọkùnrin náà jáde ó sì lọ.

25 Nígbà náà ó sì wọlé wá ó sì dúró níwájú ọ̀gá rẹ̀ Èlíṣà.“Níbo ni o ti wà Géhásì?” Èlíṣà bèèrè.“Ìránṣẹ́ rẹ kò lọ sí ibìkan kan.” Géhásì dá a lóhùn.

26 Ṣùgbọ́n Èlíṣà wí fún un pé, “Ẹ̀mí mi kò ha wà pẹ̀lú rẹ nígbà tí ọkùnrin náà sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ láti pàdé rẹ? Ṣé àsìkò tí ó yẹ láti gba owó nìyìí, tàbí láti gba aṣọ, ọgbà-ólífì, ọgbà àjàrà, àgùntàn, màlúù tàbí ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin?

27 Ẹ̀tẹ̀ Námánì yóò rọ̀mọ́ ọ àti sí irú ọmọ rẹ títí láé.” Nígbà náà Géhásì kúrò níwájú Èlíṣà, ó sì di adẹ́tẹ̀, ó sì funfun gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.