1 Àwọn ọmọ wòlíì sọ fún Èlíṣà pé, “Wò ó, ní ibi tí a ti pàdé pẹ̀lú rẹ, ó kéré fún wa.
2 Jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí Jọ́dánì, ní ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti le rí ọ̀pá kan, jẹ́ kí àwa kí ó kọ́lé síbẹ̀ fún wa láti gbé.”Ó sì wí pé, “lọ.”
3 Nígbà náà ni ọ̀kan lára wọn wí pé, “Ṣé ìwọ kò ní jọ̀wọ́ wa pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ?”“Èmi yóò lọ,” Èlíṣà dá a lóhùn.
4 Ó sì lọ pẹ̀lú wọn.Wọ́n sì lọ sí Jọ́dánì wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gé igi