2 Jẹ́ kí àwa kí ó lọ sí Jọ́dánì, ní ibi tí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti le rí ọ̀pá kan, jẹ́ kí àwa kí ó kọ́lé síbẹ̀ fún wa láti gbé.”Ó sì wí pé, “lọ.”
3 Nígbà náà ni ọ̀kan lára wọn wí pé, “Ṣé ìwọ kò ní jọ̀wọ́ wa pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ?”“Èmi yóò lọ,” Èlíṣà dá a lóhùn.
4 Ó sì lọ pẹ̀lú wọn.Wọ́n sì lọ sí Jọ́dánì wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní gé igi
5 Bí ọ̀kan ṣe gé igi náà, àáké irin náà bọ́ sínú omi, ó kí gbe sókè pé, o! Olúwa mi, “mo yá a ni”
6 Ènìyàn Ọlọ́run sì béèrè pé, “Níbo ni ó bọ́ sí?” Nígbà tí ó fi ibẹ̀ hàn án, Èlíṣà ge igi kan ó sì jù ú síbẹ́, ó sì mú irin náà fò lójú omi.
7 Ó wí pé, “Gbé e jáde” Nígbà náà ọkùnrin náà na ọwọ́ rẹ̀ jáde ó sì mú un.
8 Nísinsìn yìí ọba Árámù ó wà ní ogun pẹ̀lú Ísírẹ́lì ó sì bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ gbérò, ó wí pé “Èmi yóò ṣe ibùdó mi sí ibí yìí nínú èyí náà àti bí ibí yìí.”