30 Nígbà tí ọba gbọ́ ọ̀rọ̀ obìnrin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Gẹ́gẹ́ bí ó sì ti ń kọjá lọ sí orí odi, àwọn ènìyàn wò ó níbẹ̀ ní abẹ́, ó ní aṣọ ọ̀fọ̀ ní ara rẹ̀.
31 Ó sì wí pé, “Kí Olúwa kí ó fi ìyà jẹ mí, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ dájúdájú, pé orí ọmọkùnrin Èlíṣà ọmọ Sáfátì kì ó wà ní ọrùn rẹ̀ ní òní!”
32 Nísinsìnyí Èlíṣà jókòó ní ilé rẹ̀ àwọn àgbààgbà náà jókòó pẹ̀lú rẹ̀. Ọba sì rán oníṣẹ́ ṣíwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó tó dé ibẹ̀, Èlíṣà sọ fún àwọn àgbààgbà pé, “Ṣé èyin kò rí bí apànìyàn ti ń rán ẹnìkan láti gé orí mi kúrò? Ẹ wò ó, nígbà tí ìránṣẹ́ náà bá dé, ẹ ti ìlẹ̀kùn kí ẹ sì dì í mú ṣinṣin nítorí rẹ̀, kì í ṣe ìró ẹsẹ̀ ọ̀gá rẹ̀ wà lẹ́yìn rẹ?”
33 Nígbà tí ó sì ń sọ̀rọ̀ sí wọn, ìránṣẹ́ náà sọ̀kalẹ̀ wá bá a. Ọba náà sì wí pé, “Ibi yìí láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni. Kí ni ó dé tí èmi yóò fi dúró de Olúwa sí i?”