2 Ọba 8:12-18 BMY

12 “Kí ni ó dé tí Olúwa mi fi ń sunkún?” Hásáélì bèèrè.“Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Ísírẹ́lì,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.”

13 Hásáélì sì wí pé. “Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ, ajá lásán làsàn yóò ṣe ṣe irú nǹkan ńlá bẹ́ẹ̀?”“Olúwa ti fi hàn mí pé ìwọ ni yóò jẹ ọba síríà,” Èlíṣà dá a lóhùn.

14 Nígbà náà Hásáélì fi Èlíṣà sílẹ̀ ó sì padà sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀. Nígbà tí Bẹnihádádi bèèrè, “Kí ni ohun tí Èlíṣà sọ fún ọ?” Hásáélì dá a lóhùn, “Ó sọ fún mi wí pé ìwọ yóò sàn nítòótọ́.”

15 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì ó mú aṣọ tí ó nípọn, ó sì kì í bọ inú omi ó sì tẹ̀ẹ́ sí ojú ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú. Nígbá náà Hásáélì sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

16 Ní ọdún karùn-ún ti Jórámù ọmọ Áhábù ọba Ísírẹ́lì, nígbà tí Jéhóṣáfátì jẹ́ ọba Júdà, Jéhórámù ọmọ Jéhóṣáfátì bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Júdà.

17 Ó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún mẹ́jọ.

18 Ó sì rìn ní ọ̀nà ọba Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti lọ, nítorí ó fẹ́ ọmọbìnrin Áhábù ó sì ṣe ohun búburú níwájú Olúwa.