21 Bẹ́ẹ̀ ni Jéhórámù lọ sí Ṣáírì pẹ̀lú gbogbo kẹ̀kẹ́ rẹ̀. Àwọn ará Édómù sì yí i ká àti kẹ̀kẹ́ àwọn olórí wọn, ṣùgbọ́n ó dìde dúró ní òru; àwọn ogun rẹ̀ síbẹ̀ síbẹ̀, sá padà lọlé.
22 Títí ó fi di òní, Édómù wà nínú ọ̀tẹ̀ lórí Júdà, Líbinà ṣọ̀tẹ̀ ní àkókò kan náà.
23 Gẹ́gẹ́ bí fún iṣẹ́ mìíràn ti ìjọba Jórámù, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Júdà?
24 Jórámù sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ a sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú Dáfídì, Áhásáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
25 Ní ọdún méjìlá Jórámù ọmọkùnrin Áhábù ọba Ísírẹ́lì, Áhásáyà ọmọkùnrin Jéhórámù ọba Júdà bẹ̀rẹ̀ ìjọba rẹ̀.
26 Áhásáyà jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó di ọba. Ó sì jọba ní ọdún kan ní Jérúsálẹ́mù. Orúkọ ìyá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Átalíàh, ọmọbìnrin Ómírìe ọba Ísírẹ́lì.
27 Nígbà tí ó rin ọ̀nà ilé Áhábù ó sì ṣe búburú níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ilé Áhábù ti ṣe, nítorí ó tan nípa ìgbéyàwó sí ìdílé Áhábù.