2 Ọba 8:6-12 BMY

6 Ọba bèèrè lọ́wọ́ obìnrin náà nípa rẹ̀, ó sì sọ fún un.Ó sì yan ìjòyè kan fún ún fún ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì wí fún un pé, “Ẹ fún un padà gbogbo ohun tí ó bá jẹ́ tirẹ̀, àti pẹ̀lú gbogbo èrè ilé rẹ̀ fún ún láti ọjọ́ tí ó ti kúrò ní ìlú títí di àsìkòyí.”

7 Èlíṣà lọ sí Dámásíkù, Bẹni-Hádádì ọba Ṣíríà ń ṣe àìsàn. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba pé, “Ènìyàn Ọlọ́run ti wá láti gbogbo ọ̀nà òkè síbí”,

8 ó sì wí fún Hásáélì pé, “Mú ẹ̀bùn kan pẹ̀lú rẹ láti lọ pàdé ènìyàn Ọlọ́run. Kí o sì béèrè Olúwa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn yìí?”

9 Hásáélì lọ láti pàdé Èlísà, ó mú lọ pẹ̀lú rẹ̀ ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí ogójì ẹrù ìbákasìẹ tí gbogbo ìní tí ó dára jù fún wíwò ti Dámásíkù, ó sì wọlé lọ ó sì dúró níwájú rẹ̀, ó sì wí pé, “Ọmọ rẹ Bénhádádì ọba Ṣíríà rán mi láti béèrè pé, ‘Ṣé èmi yóò sàn nínú àìsàn mi yìí?’ ”

10 Èlíṣà da á lóhùn pé, “Lọ kí o lọ sọ fún un pé, ‘Ìwo ìbá sàn ní tòótọ́’; ṣùgbọ́n Olúwa ti fi hàn mí pé nítòotọ́ òun yóò kú.”

11 Ó sì ranjú mọ́ ọn pẹ̀lú àtẹjúmọ́ gidigidi títí tí ojú fi ti Hásáélì. Nígbà náà ènìyàn Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí ní sunkún.

12 “Kí ni ó dé tí Olúwa mi fi ń sunkún?” Hásáélì bèèrè.“Nítorí pé èmi mọ ibi tí ìwọ yóò ṣe sí Ísírẹ́lì,” ó sì dáhùn pé, “Ìwọ yóò fi iná si odi agbára wọn, ìwọ yóò, pa àwọn ọ̀dọ́ ọmọkùnrin wọn pẹ̀lú idà, ìwọ yóò kọlù àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ìwọ ó sì fọ́ wọn túútúú, ìwọ o sì la inú àwọn aboyún wọn.”