4 Hánúnì sì mú àwọn ìránṣẹ Dáfídì ó fá apákan irungbọ̀n wọn, ó sì gé ààbọ̀ kúró ní agbádá wọn, títí ó fí dé ìdí wọn, ó sì rán wọn lọ.
5 Wọ́n sì sọ fún Dáfídì, ó sì ránṣẹ́ lọ pàdé wọn, nítorí tí ojú ti àwọn ọkùnrin náà púpọ̀: ọba sì wí pé, “Ẹ dúró ní Jẹ́ríkò títí irungbọ̀n yín yóò fi hù, nígbà náà ni kí ẹ tó máa bọ̀.”
6 Àwọn ọmọ Ámónì sì ri pé, wọ́n di ẹni ìríra níwájú Dáfídì, àwọn ọmọ Ámónì sì ránṣẹ, wọ́n sì fi owó bẹ́ ogún àwọn ará Síríà ti Bẹtire-hóhù; àti Síríà ti Sóbà, ẹgbaàwá ẹlẹ́sẹ̀ àti ti ọba Máákà, ẹgbẹ̀run ọkùnrin àti ti Isítóbù ẹgbàafà ọkùnrin lọ́wẹ̀.
7 Dáfídì sì gbọ́, ó sì rán Jóábù, àti gbogbo ogún àwọn ọkùnrin alágbára.
8 Àwọn ọmọ Ámónì sì jáde, wọ́n sì tẹ́ ogún ní ẹnu odi; ará Síríà ti Sóbà, àti ti Réhóbù, àti Ísítóbù, àti Máákà, wọ́n sì tẹ ogun ni pápá fún ara wọn.
9 Nígbà tí Jóábù sì ríi pé ogun náà dojú kọ òun níwájú àti lẹ́yìn, ó sì yàn nínú gbogbo àwọn akíkanjú ọkùnrin ní Ísírẹ́lì, ó sì tẹ́ ogun kọjú sí àwọn ará Síríà.
10 Ó sì fi àwọn ènìyàn tí ó kù lé Ábíṣáì àbúrò rẹ̀ lọ́wọ́, kí ó lè tẹ ogun kọjú sí àwọn ọmọ Ámónì.