23 Jóábù sì dìde, ó sì lọ sí Géṣúrì, ó sì mú Ábúsálómù wá sí Jérúsálẹ́mù.
24 Ọba sì wí pé, “Jẹ́ kí ó yípadà lọ sí ilé rẹ̀, má ṣe jẹ́ kí ó rí ojú mi.” Ábúsálómù sì yípadà sí ilé rẹ̀, kò sì rí ojú ọba.
25 Kó sì sí arẹ́wà kan ní gbogbo Ísírẹ́lì tí à bá yìn bí Ábúsálómù: láti àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ̀ títí dé àtàrí rẹ̀ kò sí àbùkù kan lára rẹ̀.
26 Nígbà tí ó bá sì rẹ́ irun orí rẹ̀ (nítorí pé lọ́dọ̀ọdún ni òun máa ń rẹ́ ẹ. Nígbà tí ó bá wúwo fún un, òun a sì máa rẹ́ ẹ) òun sì wọn irun orí rẹ̀, ó sì jásí igba ṣẹ́kẹ́lì nínú òṣùwọ̀n ọba.
27 A sì bí ọmọkùnrin mẹ́ta fún Ábúsálómù àti ọmọbìnrin kan ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Támárì: òun sì jẹ́ obìnrin tí ó lẹ́wà lójú.
28 Ábúsálómù sì gbé ni ọdún méjì ní Jérúsálẹ́mù kò sì rí ojú ọba.
29 Ábúsálómù sì ránṣẹ́ sí Jóábù, láti rán an sí ọba: ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀; ó sì ránṣẹ́ lẹ́ẹ̀kejì òun kò sì fẹ́ wá.