1 Dáfídì sì kọ ọ̀rọ̀ orin yìí sí Olúwa ní ọjọ́ tí Olúwa gbà á kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù.
2 Ó sì wí pé,“Olúwa ni àpáta mi, àti Olùgbàlà mi;
3 Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò,àti ìwọ ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi,àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi;ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.
4 Èmi képe Olúwa, tí ó yẹ láti máa yìn,ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.