1 Ọ̀rọ̀ Nehemáyà ọmọ Hakaláyà:Ní oṣù kíṣíléfì ní ogún ọdún (ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba Páṣíà) nígbà tí mo wà ní ààfin Ṣúṣánì,
2 Hánánì, ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin mi wá láti Júdà pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kan, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tí ó ṣẹ́kù tí wọn kò kó ní ìgbèkùn, àti nípa Jérúsálẹ́mù.
3 Wọ́n sọ fún mi pé, “Àwọn tí ó kù tí a kó ní ìgbèkùn tí wọ́n sì pada sí agbégbé ìjọba wà nínú wàhálà púpọ̀ àti ẹ̀gàn. Odi Jérúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀ a sì ti fi iná ṣun ẹnu ibodè rẹ̀.”
4 Nígbà tí mo gbọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo jókòó mo sì ṣunkún. Mo ṣọ̀fọ̀, mo gbààwẹ̀, mo sì gbàdúrà fún ọjọ́ díẹ̀ níwájú Ọlọ́run ọ̀run.
5 Nígbà náà ni mo wí pé:“Olúwa, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi tí ó sì ní ẹ̀rù, tí ó ń pa májẹ̀mu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹ̀lú wọn tí ó fẹ́ẹ tí wọ́n sì ń pa àṣẹ mọ́.
6 Jẹ́ kí etíì rẹ kí ó ṣi sílẹ̀, kí ojúù rẹ kí ó sì sí sílẹ̀ láti gbọ́ àdúrà tí ìránṣẹ́ rẹ ń gbà ní iwájú rẹ ní ọ̀sán àti ní òru fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì. Mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwa ọmọ Ísírẹ́lì àti tèmi àti ti ilé baba mi, tí a ti ṣẹ̀ sí ọ.
7 Àwa ti ṣe búburú sí ọ. A kò sì pa àṣẹ ìlànà àti òfin tí ìwọ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ mọ́.