14 Nígbà náà ni mo lọ sí ẹnu ibodè oríṣun àti sí adágún omi ọba, ṣùgbọ́n kò sí ààyè tó fún ẹranko mi láti kọjá;
15 Bẹ́ẹ̀ ni mo gòkè àfonífojì ní òru, mo ń wo odi. Ní ìparí, mo padà ṣẹ́yìn, mo sì tún wọlé láti ibodè àfonífojì.
16 Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà.
17 Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a wọ̀: Jérúsálẹ́mù wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jérúsálẹ́mù mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”
18 Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi.Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí.
19 Ṣùgbọ́n nígbà tí Ṣáńbálátì ará a Hórónì, Tòbáyà ara olóyè Ámónì àti Géṣémù ará a Arábíyà gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?”
20 Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohun kóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jérúsálẹ́mù.”