15 Ẹnu Ìbodè Oríṣun ni Ṣálúnì ọmọ Kólí-Hóṣì, alákóṣo agbégbé Mísípà tún mọ. Ó tún ún mọ, ó kan òrùlé e rẹ̀ yíká, ó gbé àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ àwọn ìdáiùú ìlẹ̀kùn àti àwọn idẹ rẹ̀ ró sí ààyè wọn. Ó tún tún odi Adágún Ṣílóámù mọ, ní ẹ̀gbẹ́ Ọgbà Ọba, títí dé àwọn àtẹ̀gùn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ láti ìlú Dáfídì.
16 Lẹ́yìn in rẹ̀ ni, Nehemáyà ọmọ Áṣíbúkù, alákóṣo ìdajì agbégbé Bétí Ṣúrì ṣe àtúnmọ dé ibì ọ̀ọ́kan ibojì Dáfídì, títí dé adágún omi àtọwọ́dá àti títí dé ilé àwọn alágbára.
17 Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn ará a Léfì, ní abẹ́ ẹ Réhúmù ọmọ Bánì. Lẹ́gbẹ̀ ẹ́ rẹ̀ ni Hásíábíà, alákóṣo ìdajì agbégbé Kéílà ṣe àtúnṣe fún agbégbé tirẹ̀.
18 Lẹ́yìn rẹ̀ ni àwọn arákùnrin wọn ṣe àtún-ṣe, Báfáyì ọmọ Hénádádì, alákóṣo àwọn ìdajì agbégbé kéílà.
19 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Éṣérì ọmọ Jéṣúà, alákóṣo Mísípà, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun.
20 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bárúkù ọmọ Ṣábáyì fi ìtaa tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù olórí àlùfáà.
21 Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákósì tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù títí dé òpin rẹ̀