19 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Éṣérì ọmọ Jéṣúà, alákóṣo Mísípà, tún ìbò mìíràn ṣe, láti ibìkan tí ó kojú sí ibi gíga sí ilé-ìhámọ́ra títí dé orígun.
20 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bárúkù ọmọ Ṣábáyì fi ìtaa tún apá mìíràn ṣe, láti orígun dé ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù olórí àlùfáà.
21 Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Mérémótì ọmọ Úráyà, ọmọ Hákósì tún apá mìíràn ṣe, láti ẹnu ọ̀nà ilé Élíáṣíbù títí dé òpin rẹ̀
22 Àtúnṣe tí a tún tún ṣe lẹ́yìn rẹ̀ ní àwọn àlùfáà ní àyíká agbègbè tún ṣe.
23 Lẹ́yìn wọn ni Bẹ́ńjámínì àti Háṣíbù tún èyí ti iwájú ilé wọn ṣe; lẹ́yìn wọn ni, Ásáríyà ọmọ Máṣéyà ọmọ Ananíyà tún ti ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ ṣe.
24 Lẹ́yìn rẹ̀ ni Bínúì ọmọ Hénádádì tún apá mìíràn ṣe, láti ilé Ásáríyà dé orígun àti kọ̀rọ̀,
25 àti Pálálì ọmọ Úṣáì tún ọ̀kánkán orígun ṣe àti ilé ìṣọ́ tí ó yọ sóde láti ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ààfin tòkè lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbégbé àwọn olùṣọ́. Lẹ́yìn rẹ̀ ni, Pédáyà ọmọ Párósì