1 Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì rì àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Léfì.
2 Mo fún Hánánì arákùnrin mi pẹ̀lú Hananáyà olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòótọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ.
3 Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ sí ìlẹ̀kùn Jérúsálẹ́mù títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”
4 Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́.
5 Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà:
6 Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì ti kó ní ìgbékùn (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà, olúkúlùkù sí ìlúu rẹ̀.
64 Àwọn wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í nibẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́;