10 Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è ṣọ wí pé,“Wòó! Ohun tuntun ni èyí”?Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́Ó ti wà ṣáájú tiwa.
11 Kò sí ìrántí ohun ìṣáájúbẹ́ẹ̀ ni ìrantí kì yóò sí fúnohun ìkẹyìn tí ń bọ̀lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.
12 Èmi, Oníwàásù ti jẹ ọba lórí Ísírẹ́lì ní Jérúsálẹ́mù rí.
13 Mo fi àsìkò mi sílẹ̀ láti kọ́ àti láti ṣe àwárí pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run. Háà ẹrù wúwo tí Ọlọ́run ti gbé lé àwọn ènìyàn:
14 Èmi ti rí ohun gbogbo tí ó ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ oòrùn, gbogbo rẹ̀ kò ní ìtumọ̀ bí ẹní gbìyànjú àti mú afẹ́fẹ́ ni.
15 Ohun tí ó ti wọ́ kò le è ṣe é tọ́ mọ́,ohun tí kò sí kò le è ṣe é kà.
16 Mo rò nínú ara mi, “Wòó, mo ti dàgbà, ọgbọ́n mi sì ti pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tí ó ti ṣe alákòóṣo Jérúsálẹ́mù síwájú mi lọ, mo ti ní ìrírí púpọ̀ nípa ọgbọ́n àti ìmọ̀.”