1 Fún àkàrà rẹ ṣórí omi,nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò ríi padà
2 Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú,nítorí ìwọ kò mọ ohun—ìparun tí ó le è wá ṣórí ilẹ̀
3 Bí àwọ̀ṣánmọ̀ bá kún fún omi,ayé ni wọ́n ń rọ òjò síBí igi wó sí ì hà Gúṣù tàbí sí ìhà àríwáníbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.
4 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn;ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọ̀ṣańmọ̀ kò ní kórè.
5 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́tàbí mọ bí ara tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́runẹlẹ́dàá ohun-gbogbo.