19 Ọgbọ́n máa ń mú kí Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbáraju alákòóṣo mẹ́wàá lọ ní ìlú
20 Kò sí olódodo ènìyàn kan láyétí ó ṣe ohun tí ó tọ́ tí kò dẹ́ṣẹ̀ rárá.
21 Má ṣe kíyè sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ènìyàn ń sọbí bẹ́ẹ̀ kọ́, o le è gbọ́ pé ìránṣẹ́ rẹ ń ṣépè fún ọ.
22 Tí o sì mọ̀ nínú ọkàn rẹpé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣépè fún àwọn ẹlòmìíràn.
23 Gbogbo èyí ni mo ti dánwò nípa ọgbọ́n, tí mo sì wí pé,“Mo pinnu láti jẹ́ ọlọgbọ́n”ṣùgbọ́n eléyìí ti jù mí lọ.
24 Ohun tí ó wù kí ọgbọ́n le è jẹ́,ó ti lọ jìnnà, ó sì jinlẹ̀ta ni ó le è ṣe àwárí rẹ̀?
25 Mó wá ròó nínú ọkàn mi láti mọ̀,láti wá àti láti ṣàwárí ọgbọ́nàti ìdí ohun gbogbo, àti láti mọ àgọ́ ìwàbúburú àti ti ìsínwín tàbí òmùgọ̀.