20 Sì kíyèsí i, ìwọ ó yadi, ìwọ kì yóò sì le fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.”
21 Àwọn ènìyàn sì ń dúró de Sakaráyà, ẹnu sì yà wọ́n nítorí tí ó pẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì.
22 Nígbà tí ó sì jáde wá, òun kò le bá wọn sọ̀rọ̀. Wọn sì kíyèsí wí pé ó ti rí ìran nínú tẹ́ḿpílì. ó sì ń se àpẹẹrẹ sí wọn, nítorí tí ó yadi.
23 Ó sì ṣe, nígbà tí ọjọ́ iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ pé, ó lọ sí ilé rẹ̀.
24 Lẹ́yìn èyí ni Èlísábẹ́tì aya rẹ̀ lóyún, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́ ní oṣù márùn-ún, ó ní,
25 Ó sì wí pé “Báyìí ni Olúwa ṣe fún mi ní ọjọ́ tí ó ṣíjú wò mí, láti mú ẹ̀gàn mi kúrò láàrin àwọn ènìyàn.”
26 Ní oṣù kẹfà Ọlọ́run sì rán áńgẹ́lì Gébúríẹ́lì sí ìlú kan ní Gálílì, tí à ń pè ní Násárẹ́tì,