1 Àwọn kan sì wá ní àkókò náà tí ó sọ ti àwọn ará Gálílì fún un, ẹ̀jẹ̀ ẹni tí Pílátù dàpọ̀ mọ́ ti wọn.
2 Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ṣe bí àwọn ará Gálílì wọ̀nyí ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo àwọn ará Gálílì lọ, nítorí wọ́n jẹ iru ìyà báwọ̀n-ọ́n-nì?
3 Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò se pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
4 Tàbí àwọn méjìdínlógún, tí ilé-ìsọ́ ní Sílóámù wólù, tí ó sì pa wọ́n, ẹ̀yin sebí wọ́n ṣe ẹlẹ́sẹ̀ ju gbogbo àwọn ènìyàn tí ń bẹ ní Jerúsálémù lọ?
5 Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́: bí kò ṣe pé ẹ̀yin ronúpìwàdà, gbogbo yín ni yóò ṣègbé bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”
6 Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé: “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan.
7 Ó sì wí fún olùsọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sáàwòó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’
8 “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ lí ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i:
9 Bí ó bá sì so èso, gẹ́gẹ́: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”
10 Ó sì ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù kan ní ọjọ́ ìsinmi.
11 Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹmí àìlera, láti ọdún méjìdínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe.
12 Nígbà tí Jésù rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.”
13 Ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ lé e: Lójúkan náà a sì ti sọ ọ́ di títọ́, ó sì ń yin Ọlọ́run lógo.
14 Olórí sínágọ́gù sì kún fún ìrúnnú, nítorí tí Jésù múni láradá ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pé, Ijọ́ mẹ́fà ní ń bẹ tí a fi í ṣiṣẹ́: nínú wọn ni kí ẹ̀yin kí ó wá kí á ṣe dídá ara yín, kí ó má se ní ọjọ́ ìsinmi.
15 Nígbà náà ni Olúwa dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹ̀yin àgàbàgebè, olúkúlùkù yín kì í tú màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ kúrò níbùso, kì í sì í fà á lọ mumi lí ọjọ́ ìsinmi.
16 Kò sì yẹ kí a tú obìnrin yìí tí í se ọmọbìnrin Ábúráhámù sílẹ̀ ní ìdè yìí ní ọjọ́ ìsinmi, ẹni tí sàtánì ti dè, sáà wò ó láti ọdún májìdínlógún yìí wá?”
17 Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, ojú ti gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ̀: gbogbo ìjọ ènìyàn sì yọ̀ fún ohun ògo gbogbo tí ó ṣe láti ọwọ́ rẹ̀ wá.
18 Ó sì wí pé, “Kíni ìjọba Ọlọ́run jọ? Kíni èmi ó sì fi wé?
19 Ó dàbí hóró músítádì, tí ọkùnrin kan mú, tí ó sì sọ sínú ọgbà rẹ̀; tí ó sì hù, ó sì di igi ńlá; àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé orí ẹ̀ka rẹ̀.”
20 Ó sì tún wí pé, “Kíli èmi ìbá fi ìjọba Ọlọ́run wé?
21 Ó dàbí ìwúkàrà, tí obìnrin kan mú, tí ó fi sínú òsùnwọ̀n ìyẹ̀fun mẹ́ta, títí gbogbo rẹ̀ ó fi di wíwú.”
22 Ó sì ń la àárin ìlú àti ìletò lọ, ó ń kọrin, ó sì ń rìn lọ sí ìhà Jerúsálémù.
23 Ẹnìkan sì bi í pé, Olúwa, díẹ̀ ha ni àwọn tí a ó gbàlà?Ó sì wí fún wọn pé,
24 “Ẹ làkàkà láti gba ojú ọ̀nà tóóró wọlé: nítorí mo wí fún yín, ènìyàn púpọ̀ ni yóò wá ọ̀nà láti wọ̀ ọ́, wọn kì yóò sì lè wọlé.
25 Nígbà tí baálé ilé bá dìde lẹ́ẹ̀kan fù ú, tí ó bá sí ìlẹ̀kùn ẹ̀yin ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í dúró lóde, tí ẹ ó máa kan ìlẹ̀kùn, wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣí i fún wa!’“Òun ó sì dáhùn wí fún yín pé, ‘Èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá.’
26 “Nígbà náà ni ẹ̀yin ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, ‘Àwa ti jẹ, àwa sì ti mu níwájú rẹ, ìwọ sì kọ́ni ní ìgboro ìlú.’
27 “Òun ó sì wí pé, ‘Èmi wí fún yín èmi kò mọ̀ ibi tí ẹ̀yin ti wá; ẹ lọ kúrò lọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.’
28 “Níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpahínkeke yóò wà, nígbà tí ẹ̀yin ó rí Ábúráhámù, àti Ísáákì, àti Jákọ́bù, àti gbogbo àwọn wòlíì, ní ìjọba Ọlọ́run, tí a ó sì ti ẹ̀yin sóde.
29 Wọn ó sì ti ilẹ̀ ìlà òòrùn, àti ìwọ̀-òòrùn wá, àti láti àríwá, àti gúsù wá, wọn ó sì jókòó ní ìjọba Ọlọ́run.
30 Sì wò ó, àwọn ẹni ẹ̀yìn ń bẹ tí yóò di ẹni iwájú, àwọn ẹni ìwájú ń bẹ tí yóò di ẹni ẹ̀yìn.”
31 Ní wákàtí kan náà, díẹ̀ nínú àwọn Farisí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Jáde, kí ìwọ sì lọ kúrò níhín-ín yìí: nítorí Hẹ́rọ́dù ń fẹ́ pa ọ́.”
32 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ lọ, kí ẹ̀yin sì sọ fún kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé, ‘Kíyèsí i, èmi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, èmi ń ṣe ìmúláradá lóní àti lọ́la, àti ní ijọ́ mẹ́ta èmi ó ṣe àṣepé.’
33 Ṣùgbọ́n èmi kò jẹ́ má rìn lóní, àti lọ́la, àti ní ọ̀túnla: kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ pé wòlíì yóò ṣègbé lẹ́yìn odi Jerúsálémù.
34 “Jerúsálémù, Jerúsálémù, ìwọ tí o pa àwọn wòlíì, tí o sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí ọ pa; nígbà mélòó ni èmi ń fẹ́ ràgà bo àwọn ọmọ rẹ, bí àgbébọ̀ ti í ràgà bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fẹ́!
35 Sá wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro: lóòtóọ́ ni mo sì wí fún yín, Ẹ̀yin kì yóò sì rí mi títí yóò fi di àkókò tí ẹ̀yin ó wí pé, ‘Olùbùkún ni ẹni tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa.’ ”