Lúùkù 22 BMY

Júdásì Gbà Láti Da Jésù

1 Àjọ ọdún àkàrà àìwú tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́rẹ́fẹ́.

2 Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.

3 Sàtánì sì wọ inú Júdásì, tí à ń pè ní Isíkáríọ́tù, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá.

4 Ó sì mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n, ó lọ láti bá àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ gbérò pọ̀, bí òun yóò tí fi í lé wọn lọ́wọ́.

5 Wọ́n sì yọ̀, wọ́n sì bá a dá májẹ̀mu láti fún un ní owó.

6 Ó sì gbà; ó sì ń wá àkókò tí ó wọ̀, láti fi í lé wọn lọ́wọ́ láìsí ariwo.

Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa

7 Ojọ́ àkàrà àìwú pé, nígbà tí wọ́n ní láti ṣe ìrúbọ ìrékọjá.

8 Ó sì rán Pétérù àti Jòhánù, wí pé, “Ẹ lọ pèsè ìrékọjá fún wa, kí àwa ó jẹ”

9 Wọ́n sì wí fún un pé, “Níbo ni ìwọ ń fẹ́ kí á pèsè sílẹ̀?”

10 Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ẹ̀yin bá ń wọ ìlú lọ, ọkùnrin kan tí ó ru iṣà omi yóò pàdé yín, ẹ bá a lọ sí ilé tí ó bá wọ̀,

11 kí ẹ sì wí fún baálé ilé náà pé, ‘Olùkọ́ wí fún ọ pé: Níbo ni gbọ̀ngàn àpèjẹ náà gbé wà, níbi tí èmi ó gbé jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’

12 Òun ó sì fi gbọ̀ngàn ńlá kan lókè hàn yín, tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́: níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin pèsè sílẹ̀.”

13 Wọ́n sì lọ wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó tí sọ fún wọn: wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀.

14 Nígbà tí àkókò sì tó, ó jókòó àti àwọn àpósítélì pẹ̀lú rẹ̀.

15 Ó sì wí fún wọn pé, “Tinú-tinú ni èmi fẹ́ fi bá yín jẹ ìrékọjá yìí, kí èmi tó jìyà:

16 Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò jẹ nínú rẹ̀ mọ́, títí a ó fi mú un ṣẹ ní ìjọba Ọlọ́run.”

17 Ó sì gba aago, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó wí pé, “Gba èyí, kí ẹ sì pín in láàrin ara yín.

18 Nítorí mo wí fún yín, Èmi kì yóò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí ìjọba Ọlọ́run yóò fi dé.”

19 Ó sì mú àkàrà, nígbà tí ó sì ti dúpẹ́ ó bù ú, ó sì fifún wọn, ó wí pé, “Ẹ̀yí ni ara mí tí a fifún yín: ẹ má a ṣe èyí ní ìrántí mi.”

20 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ lẹ́yìn oúnjẹ alẹ́, ó sì mú aago, ó wí pé, “Aago yìí ni májẹ̀mú tuntun nínú ẹ̀jẹ̀ mi, tí a ta sílẹ̀ fún yín.

21 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsí i, ọwọ́ ẹni tí yóò fi mí hàn wà pẹ̀lú mi lórí tábìlì.

22 Ọmọ Ènìyàn ń lọ nítòótọ́ bí a tí pinnu rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà nípasẹ̀ ẹni tí a gbé ti fi í hàn.”

23 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bèèrè láàrin ara wọn, tani nínú wọn tí yóò ṣe nǹkan yìí.

24 Ìjà kan sì ń bẹ láàrin wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí níńu wọn.

25 Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore.

26 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.

27 Nítorí tani ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí óunjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrin yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ.

28 Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi,

29 Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi:

30 Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.”

31 Olúwa sì wí pé, “Símónì, Símónì, wò ó, Sàtánì fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí àlìkámà:

32 Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

33 Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”

34 Ó sì wí pé, “Mo wí fún ọ, Pétérù, àkùkọ kì yóò kọ lónìí-ín tí ìwọ ó fi sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, ìwọ kò mọ̀ mí.”

35 Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí mo rán yín lọ láìní àpò-owó, àti àpò, àti bàtà, ọ̀dá ohun kan dá yín bí?”Wọ́n sì wí pé, “Rárá!”

36 Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé, “Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹni tí ó bá ní àpò owó kí ó mú un, àti àpò pẹ̀lú; ẹni tí kò bá sì ní idà, kí ó ta aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi ra ìkan.

37 Nítorí mo wí fún yín pé, ‘Èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ kò lè ṣe kí ó má ṣẹ lára mi, A sì kà á mọ́ àwọn arúfin.’ Nítorí àwọn ohun wọ̀nyí nípa ti èmi yóò ní ìmúṣẹ.”

38 Wọ́n sì wí pé, “Olúwa, sá wò ó, idà méjì ń bẹ níhín-ín yìí!”Ó sì wí fún wọn pé, “Ó tó.”

Jésù Gbàdúrà Lórí Òkè Ólívì

39 Ó sì jáde, ó sì lọ bí ìṣe rẹ̀ sí òkè ólífì, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

40 Nígbà tí ó wà níbẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹwọ̀.”

41 Ó sì fi wọ́n sílẹ̀ níwọ̀n ìsọ-òkò kan, ó sì kúnlẹ̀ ó sì ń gbàdúrà.

42 Wí pé, “Baba, bí ìwọ bá fẹ́, gba ago yìí lọ́wọ́ mi: ṣùgbọ́n ìfẹ́ ti èmi kọ́, bí kò ṣe tìrẹ ni kí à ṣe.”

43 Ańgẹ́lì kan sì yọ sí i láti ọ̀run wá, ó ń gbà á ní ìyànjú.

44 Bí ó sì ti wà nínú gbígbóná ara ó ń gbàdúrà sí i kíkankíkan; òógùn rẹ̀ sì dàbí ìró ẹ̀jẹ̀ ńlá, ó ń kán sílẹ̀.

45 Nígbà tí ó sì dìde kúrò ní ibi àdúrà, tí ó sì tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá ó bá wọn, wọ́n ń sùn fún ìbànújẹ́.

46 Ó sì wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ yin ń sùn sí? Ẹ dìde, ẹ máa gbàdúrà, kí ẹ̀yin má ṣe bọ́ sínú ìdẹ́wò.”

Wọ́n Mú Jésù

47 Bí ó sì ti ń sọ lọ́wọ́, kíyèsí i, ọ̀pọ̀ ènìyàn, àti ẹni tí a ń pè ní Júdásì, ìkan nínú àwọn méjìlá, ó ṣáájú wọn, ó súnmọ́ Jésù láti fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

48 Jesù sì wí fún un pé, “Júdásì, ìwọ yóò ha fi ìfẹnukonu fi Ọmọ ènìyàn hàn?”

49 Nígbà tí àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń wo bí nǹkan yóò ti jásí, wọ́n bi í pé, “Olúwa kí àwá fi idà ṣá wọn?”

50 Ọ̀kan nínú wọn sì fi idà ṣá ọmọ-ẹ̀yìn olórí àlùfáà, ó sì gé etí ọ̀tún rẹ̀ sọnù.

51 Ṣùgbọ́n Jésù dáhùn ó wí pé, “Ẹ fi í sílẹ̀ báyìí ná.” Ó sì fi ọwọ́ tọ́ ọ ní etí, ó sì wò ó sàn.

52 Jésù wí fún àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ḿpìlì, àti àwọn alàgbà, tí wọ́n jáde tọ̀ ọ́ wá pé, “Ẹ̀yin ha jáde wá pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ bí ẹni tọ ọlọ́ṣà wá?

53 Nígbà tí èmi wà pẹ̀lú yín lójojúmọ́ ní tẹ́ḿpílì, ẹ̀yin kò na ọwọ́ mú mi: ṣùgbọ́n àkókò ti yín ni èyí, àti agbára òkùnkùn.”

Pétérù ṣẹ́ Jésù

54 Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Pétérù tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè.

55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrin gbọ̀ngàn, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Pétérù jokòó láàrin wọn.

56 Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”

58 Kò pẹ́ lẹ̀yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ọkùnrin yìí, Èmi kọ́.”

59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Gálílì ní í ṣe.”

60 Ṣùgbọ́n Pétérù wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ!

61 Olúwa sì yípadà, ó wo Pétérù. Pétérù sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.”

62 Pétérù sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Àwọn Ẹ̀sọ́ Ń Gan Jésù

63 Ó sì ṣe, àwọn ọkùnrin tí wọ́n mú Jésù, sì fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n lù ú.

64 Nígbà tí wọ́n sì dì í ní ojú, wọ́n lù ú níwájú, wọ́n ń bi í pé, “Sọ tẹ́lẹ̀! Ta ni ó lù ọ́?”

65 Wọ́n sì sọ ọ̀pọ̀ ohun búburú mìíràn sí I, láti fi ṣe ẹlẹ́yà.

Jésù Níwájú Pílátù Àti Hẹ́rọ́dù

66 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, ìjọ àwọn alàgbà àwọn ènìyàn péjọ pọ̀, àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, wọ́n sì fà á lọ sí àjọ wọn, wọ́n ń wí pé,

67 “Bí ìwọ́ bá jẹ́ Kírísítì náà? Sọ fún wa!”Ó sì wí fún wọn pé, “Bí mo bá wí fún yín, ẹ̀yin kì yóò gbàgbọ́;

68 Bí mo bá sì bi yín léèrè pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yóò dá mi lóhùn, (bẹ́ẹ̀ ni ẹ kì yóò fi mí sílẹ̀ lọ).

69 Ṣùgbọ́n láti ìsinsinyìí lọ ni ọmọ-ènìyàn yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára Ọlọ́run.”

70 Gbogbo wọn sì wí pé, “Ìwọ ha ṣe Ọmọ Ọlọ́run bí?”Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin wí pé, èmi ni.”

71 Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀rí wo ni àwa tún ń fẹ́ Àwa tìkarawa sáà ti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀!”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24