1 Jésù sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jọ́dánì wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù;
2 Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ Èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.
3 Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”
4 Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan.’ ”
5 Lójú kan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀-ọba ayé hàn án.
6 Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún.
7 Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”
8 Jésù sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Sátánì, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”
9 Èsu sì mú un lọ sí Jerúsálémù, ó sì gbé e lé ṣóńṣo tẹ́ḿpílì, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí:
10 A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ,láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ: (fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pa ọ́ mọ́)
11 Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
12 Jésù sì dahùn ó wí fún un pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”
13 Nígbà tí Èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ di sáà kan.
14 Jésù sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Gálílì: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
15 Ó sì ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
16 Ó sì wá sí Násárẹ́tì, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú sínágọ́gù lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé.
17 A sì fi ìwé wòlíì Àìsáyà fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:
18 “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi,Nítorí tí ó fi àmì òróró yàn míláti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòsì.Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àtiìtúnríran fún àwọn afọ́jú,àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,
19 Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”
20 Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú sínágọ́gù sì tẹjúmọ́ ọn.
21 Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónì-ín ìwé-Mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”
22 Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Jósẹ́fù kọ́ yìí?”
23 Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwé yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwá gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapanáúmù, ṣe é níhín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”
24 Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́ gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.
25 Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó pípọ̀ ni ó wà ní Ísírẹ́lì nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo;
26 Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Èlíjà sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sáréfátì, ìlú kan ní Ṣídónì.
27 Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Ísírẹ́lì nígbà wòlíì Èlíṣà; kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Námánì ará Síríà.”
28 Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú sínágọ́gù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú wọ́n ru ṣùṣù,
29 Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè taari rẹ̀ ní ògèdèǹgbé.
30 Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrin wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.
31 Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.
32 Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàsẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.
33 Ọkùnrin kan sì wà nínú Sínágọ́gù, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara,
34 “Ó ní, kíní ṣe tàwa tìrẹ, Jésù ará Násárẹ́tì? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”
35 Jésù sì bá a wí gidigidi, ó ní, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.
36 Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “ẹ̀kọ́ kínni èyi? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.”
37 Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbégbé ilẹ̀ náà yíká.
38 Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú sínágọ́gù, ó sì wọ̀ ilé Símónì lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Símónì gúnlẹ̀; wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀.
39 Ó sì sunmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́: ó sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
40 Nígbà tí oòrun sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn mú àwọn aláìsàn tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá.
41 Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kírísítì náà.
42 Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jésù sì jáde lọ ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má baà lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
43 Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàì má wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.”
44 Ó sì ń wàásù nínú sínágọ́gù ti Jùdíà.