Lúùkù 17 BMY

Ẹ̀ṣẹ̀, Ìgbàgbọ́, Iṣẹ́

1 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kò le ṣe kí ohun ìkọ̀sẹ̀ máa dé: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ẹni tí ó ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ dé.

2 Ìbá sàn fún un kí a so ọlọ mọ́ ọn ní ọrùn, kí a sì gbé e jù sínú òkun, ju kí ó mú ọ̀kan nínú àwọn kékeré wọ̀nyí kọsẹ̀

3 Ẹ máa kíyèsíra yín.“Bí arákùnrin rẹ bá sẹ̀, bá a wí; bí ó bá sì ronúpìwàdà, dárí jìn ín.

4 Bí ó bá sì sẹ̀ ọ́ ní ẹ̀rìnméje ní òòjọ́, tí ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ẹ̀rẹ̀méje ní òòjọ́ pé, ‘Mo ronúpìwàdà,’ dárí jìn ín.”

5 Àwọn àpósítélì sì wí fún Olúwa pé, “Bùsí ìgbàgbọ́ wa.”

6 Olúwa sì wí pé, “Bí ẹ̀yin bá ní ìgbàgbọ́ bí hóró irúgbìn músítadì, ẹ̀yin yóò lè wí fún igi Músítádì yìí pé, ‘Kí a fà á tu, kí a sì gbìn ọ́ sínú òkun,’ yóò sì gbọ́ ti yín.

7 “Ṣùgbọ́n tani nínú yín, tí ó ní ọmọ ọ̀dọ̀, tí ó ń tulẹ̀, tàbí tí ó ń bọ́ ẹran, tí yóò wí fún un lójú kan náà tí ó bá ti oko dé pé, ‘Lọ í jòkòó láti jẹun’?

8 Tí kì yóò kúkú wí fún un pé, ‘Pèsè ohun tí èmi yóò jẹ, sì di àmùrè, kí ìwọ kí ó máa ṣe ìránṣẹ́ fún mi, títí èmi ó fi jẹ kí èmi ó sì mu tán; lẹ́yìn náà ni ìwọ ó sì jẹ, tí ìwọ ó sì mu’?

9 Òun ó ha máa dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nítorí ó ṣe ohun tí a pa láṣẹ fún un bí? Èmi kò rò bẹ́ẹ̀.

10 Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin pẹ̀lú, nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pàṣẹ fún yín tán, ẹ wí pé, ‘Aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀ ni wá: èyí tí í se iṣẹ́ wa láti ṣe, ní àwá ti ṣe.’ ”

Ìwòsàn Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá

11 Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ sí Jerúsálémù, ó kọjá láàrin Samaríà òun Gálílì.

12 Bí ó sì ti ń wọ inú ìletò kan lọ, àwọn ọkùnrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá pàdé rẹ̀, wọ́n dúró ní òkèrè:

13 Wọ́n sì nahùn sókè, wí pé, “Jésù, Olùkọ́, ṣàánú fún wa.”

14 Nígbà tí ó rí wọn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ lọ í fi ara yín hàn fún àwọn àlùfáà.” Ó sì ṣe, bí wọ́n ti ń lọ, wọ́n sì di mímọ́.

15 Nígbà tí ọ̀kan nínú wọn rí i pé a mú Òun lára dá ó padà, ó sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run lógo.

16 Ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ̀, ó ń dúpẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀: ará Samáríà ni òun í ṣe.

17 Jésù sì dáhùn wí pé, “Àwọn mẹ́wàá kí a sọ di mímọ́? Àwọn mẹ́sàn-án ìyókù ha dà?

18 A kò rí ẹnìkan tí ó padà wá fi ògo fún Ọlọ́run, bí kò ṣe àlejò yìí?”

19 Ó sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá.”

Bíbọ̀ Ìjọba Ọlọ́run

20 Nígbà tí àwọn Farisí bi í pé, nígbà wo ni ìjọba Ọlọ́run yóò dé, ó dá wọn lóhùn pé, “Ìjọba Ọlọ́run kì í wá pẹ̀lú àmì:

21 Bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wí pé, ‘Kíyèsí i níhìn ín!’ tàbí ‘Kíyèsí i lọ́hùn ún ni!’ sáà wòó, ìjọba Ọlọ́run ń bẹ nínú yín.”

22 Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí ẹ̀yin óò fẹ́ láti rí ọ̀kan nínú ọjọ́ ọmọ ènìyàn, ẹ̀yin kì yóò sì rí i.

23 Wọ́n sì wí fún yín pé, ‘Wò ó níhìnín;’ tàbí ‘Wò ó lọ́hùn ún!’ Ẹ máa lọ, ẹ má se tẹ̀lé wọn.

24 Nítorí gẹ́gẹ́ bí mọ̀nàmọ́ná ti í kọ ní apákan lábẹ́ ọ̀run, tí sì í mọ́lẹ̀ ní apá kejì lábẹ́ ọ̀run: bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ènìyàn yóò sì rí ní ọjọ́ rẹ̀.

25 Ṣùgbọ́n kò lè sàìmá kọ́ jìyà ohun púpọ̀, kí a sì kọ̀ ọ́ lọ́dọ̀ ìran yìí.

26 “Bí ó ti rí ní ọjọ́ Nóà, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ ọmọ ènìyàn.

27 Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbéyàwó, wọ́n sì ń fa ìyàwó fún ni, títí ó fi di ọjọ́ ti Nóà wọ inú ọkọ̀ lọ, kíkún omi sì dé, ó sì run gbogbo wọn.

28 “Bí ó sì ti rí ní ọjọ́ Lọ́ọ̀tì; wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń gbìn, wọ́n ń kọ́lé;

29 Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà tí Lọ́ọ̀tì jáde kúrò ní Ṣódómù, òjò iná àti súfúrù rọ̀ láti ọ̀run wá, ó sì run gbogbo wọn.

30 “Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni yóò rí ní ọjọ́ náà tí ọmọ ènìyàn yóò farahàn.

31 Ní ọjọ́ náà, ẹni tí ó bá wà lórí ilé, tí ẹrù rẹ̀ sì ń bẹ ní ilẹ̀, kí ó má se sọ̀kalẹ̀ láti wá kó o; ẹni tí ó bá sì wà ní oko, kí ó má ṣe padà sẹ́yìn.

32 Ẹ rántí aya Lọ́ọ̀tì.

33 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wá àti gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóò sọ ọ́ nù; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì sọ ọ́ nù yóò gbà á là.

34 Mo wí fún yín, ní òru ọjọ́ náà, ènìyàn méjì yóò wà lórí àkéte kan; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.

35 Ènìyàn méjì yóò sì máa lọ ọlọ pọ̀; a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.

36 Ènìyàn méjì yóò wà ní oko, a ó mú ọ̀kan, a ó sì fi èkejì sílẹ̀.”

37 Wọ́n sì dá a lóhùn, wọ́n bi í pé, “Níbo, Olúwa?”Ó sì wí fún wọn pé, “Níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ pẹ̀lú ni Igún ì kójọ pọ̀ sí.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24