Lúùkù 2 BMY

Ìbí Jésù

1 Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Késárì Ògọ́sítù jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ìjọba Rosínú ìwé.

2 (Èyí ni ìkọ sínú ìwé ìkínní tí a ṣe nígbà tí Kíréníyù fi jẹ Baálẹ̀ Síríà.)

3 Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.

4 Jóṣéfù pẹ̀lú sì gòkè láti Násárẹ́tì ìlú Gálílì, sí ìlú Dáfídì ní Jùdéà, tí à ń pè ní Bétílẹ́hẹ́mù; nítorí ti ìran àti ìdílé Dáfídì ní í ṣe,

5 Láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú Màríà aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ tí tó bi.

6 Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun óò bí.

7 Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí àyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò.

Àwọn Olùsọ́-Àgùntàn Àti Àwọn Áńgẹ́lì

8 Àwọn olùsọ́-àgùntàn ńbẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń sọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé.

9 Ańgẹ́lì Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká: ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi.

10 Ańgẹ́lì náà sì wí fún wọn pé, Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìn rere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo.

11 Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónì-ín ní ìlú Dáfídì, tí í ṣe Kírísítì Olúwa.

12 Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ-ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.

13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ Ańgẹ́lì náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé,

14 “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run,Àti ní ayé àlààáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.”

15 Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn ańgẹ́lì náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn Olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tàrà sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀ jẹ, tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀ fún wa.”

16 Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí Màríà àti Jósẹ́fù, àti ọmọ-ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran.

17 Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí.

18 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá.

19 Ṣùgbọ́n Màríà pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀.

20 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn.

Agbé Jésù Kalẹ̀ Nínú Tẹ́ḿpílì

21 Nígbà tí ijọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù, bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ańgẹ́lì náà wá kí á tó lóyún rẹ̀ nínú.

22 Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù Màríà sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin Mósè, Josefu àti Màríà gbé Jésù wá sí Jerúsálémù láti fi í fún Olúwa;

23 (Bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”),

24 àti láti rúbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “àdàbà méjì tàbí ẹyẹlẹ́ méjì.”

25 Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan wà ní Jerúsálémù, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Ṣíméónì; ọkùnrin náà sì ṣe olóòótọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú Ísírẹ́lì: Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e.

26 A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí kírísítì Olúwa.

27 Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹ́ḿpìlì: nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé ọmọ náà Jésù wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin,

28 Nígbà náà ni Símọ́nì gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní:

29 “Olúwa alágbára, nígbàyí ni o tó jọ̀wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ,Ní àlààáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ rẹ:

30 Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná,

31 Tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo;

32 Ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà,Àti ògo Ísírẹ́lì ènìyàn rẹ̀.”

33 Ẹnu sì ya Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí.

34 Síméónì sì súre fún wọn, ó sì wí fún Màríà ìyá rẹ̀ pé: “Kíyèsí i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní Ísírẹ́lì; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀ òdì sí;

35 (Idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.”

36 Ẹnìkan sì ń bẹ, Ánà wòlíì, ọmọbìnrin Fánúénì, ní ẹ̀yà Ásérì: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúndíá rẹ̀ wá;

37 Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹ́ḿpílì, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn-án àti lóru.

38 Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè Jerúsálémù.

39 Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí Gálílì, sí Násárẹ́tì ìlú wọn.

40 Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀.

Ọ̀dọ́mọkùnrin Jésù Ni Tẹ́ḿpìlì

41 Àwọn òbi rẹ̀ a sì máa lọ sí Jerúsálémù ní ọdọọdún sí Àjọ-ìrékọjá.

42 Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí Jerúsálémù gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà.

43 Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jésù dúró lẹ́yìn ní Jerúsálémù; Jóṣéfù àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀.

44 Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn.

45 Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí Jerúsálémù, wọ́n ń wá a kiri.

46 Ó sì ṣe, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹ́ḿpílì ó jòkòó ní àárin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ti wọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè.

47 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀.

48 Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n: ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, bàbá rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbìnújẹ́ wá ọ kiri.”

49 Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri, ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ Baba mi?”

50 Ọ̀rọ̀ tí sọ kò sì yé wọn.

51 Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí Násárétì, sì fi ara balẹ̀ fún wọn: ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀.

52 Jésù sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24